DINGI OÒDUÀ TV
(Sat 29th/09/2026)
ÀJỌ SUNSHINE GRASSROOTS NETWORK,SỌ IPÁ RERE TI AWỌN NKO LÁWÙJỌ KÁÀKIRI ÌPÍNLẸ̀ ÒNDÓ,
BÁKAN NÁÀ NÍ DAYỌ AWUDE GBORIYIN FÚN MINISITA OLUBUNMI TUNJI OJO (BTO) FÚN ÌṢẸ TAKUN TAKUN TI Ó NSE

Olùdarí Gbogbogbo Sunshine Grassroots Network (SGN),Hon Dayọ Awude, ní o ṣàlàyé ipa rere ti àwọn ètò àjọ náà nko ní àwọn Ìjọba Ìbílẹ̀ méjìdínlógún(18Lg) ní Ìpínlẹ̀ Ondo.
Hon Dayọ Awude sọ ọrọ yí ni ori eto kan ni ilé isẹ Rẹdio Viral 98.5 FM,Akure, Awude sọ pé Àjọ SGN ń ṣiṣẹ́ láti dín àlàfo láàárín ìjọba àti àwọn aráàlú kù, nípa pípèsè ìrànwọ́ rere lorisirsi gbogbo fun àwọn tó nílò rẹ̀.
ÀTÌLẸ́YÌN FÚN ÀWỌN ÀGBẸ̀
Àjọ SGN ti ṣe eto iranlọwọ fún àwọn àgbè bí wọn se pín àwọn èròjà fi ó wúlò fún ìṣẹ oko bi: Ada,ọkọ̀,Bàtà ojo,ẹ̀rọ àti oogun tí wọn má nlo láti fi oko,wọn se eyi kí àwọn agbẹ lè jẹ èrè rẹpẹtẹ,gbogbo nkan wọ̀nyí,ọfẹ ni wọn npin fun awọn àgbẹ̀ oo,wọn gbé àwọn ìgbésẹ yí lati mú kí iṣẹ́ àgbẹ̀ rọrùn,kí ère wọn sì le pọ̀ sí i.
AGBEKALẸ ETO EPO ỌFẸ TINUBU
Olùdarí GBOGBOGBO SGN yi tún sọ̀rọ̀ nípa Agbekalẹ Epo Petirolu ọfẹ Tinubu (Free Fuel Initiative), ètò wá wọn tún gbe kalẹ̀ láti pèsè ìrànwọ́ fún àwọn awakọ̀,àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ ti o nílò Ẹo Petirolu àti àwọn ènìyàn tí owó tí o ń wọlé fún wọn kéré, tí iye owó epo ti o gòkè sì ńṣe àkóbá fún ọrọ aje wọn,Ó ṣàlàyé pé àwọn tó jẹ́ àǹfààní nínú ètò èpò náà ní àwọn Ọlọ́jà àti Dlreba ni ibùdó ọkọ̀ ní Ìpínlẹ̀ Òndó,àwọn lo gba ìrànwọ́ epo na.
Ó ṣàpèjúwe ètò náà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ìgbésẹ̀ pàtàkì tí Ajọ SGN ńṣe láti dín ìnira ọrọ̀ ajé,èyí tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kojú kù.
AṢỌ ITAJA ÀWỌN ỌLỌ́JÀ “APRON ATAJARE” FÚN ÀWỌN ỌLỌ́JÀ
Ohun mìíràn lára àwọn ìgbésẹ̀ tí Ọ̀gbẹ́ni Awude mẹ́nu kàn ni pípín Aṣọ Atajare ti o njẹ “Aprons”fún àwọn obìnrin oníṣòwò ọjà káàkiri Ìpínlẹ̀ Òndo.
Ó ṣàlàyé pé yàtọ̀ sí àmì àti orúkọ tí ó wà lara àwọn aṣọ apron náà, ètò náà tún jẹ́ ọ̀nà tí SGN fi ń mọyì ipa pàtàkì tí àwọn obìnrin ń kó nínú okòwò,ìṣòwò àti ọrọ̀ ajé ni àwùjọ.
Ó tún sọ pé ètò náà ń gbé ìmọ̀ àti ìkópa àwọn obìnrin ga sí i ní ìpele àwọn ará ìlú.
ETO IRO LÁGBÁRA FÚN ÀWỌN OPÓ
Ọ̀gbẹ́ni Awude tún ṣàfihàn pé SGN ní ètò ìrànwọ́ àánú tó wà fún àwọn opó káàkiri Ìpínlẹ̀ Ondo.
Nípasẹ̀ ètò náà, àwọn opó máa ń gba oríṣìíríṣìí ìrànwọ́, pẹ̀lú oúnjẹ, owó àti ohun èlò Iranwọ miran,láti dín àwọn ìṣòro tí wọ́n ń dojú kọ kù.
ATILẸYIN GIDI ÀTI ÌRÓ LÁGBÁRA TÀÀRÀ
Olùdarí Gbogbogbo yí, Hon Dayọ Awude tún ṣàlàyé pé àwọn ìgbésẹ̀ SGN kò mọ́ sí àwọn ètò tí ó n ṣe àgbékalẹ̀ nìkan.
Ó ní àjọ náà tún ń pèsè Ìró lágbára tààrà fún àwọn ènìyàn kọ̀ọ̀kan, àwọn ọdọ́ àti àwọn ènìyàn àwùjọ tí wọ́n nílò ìrànwọ́.
Àwọn ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ohun èlò bí,irinsẹ,
pẹ̀lú ète láti jẹ́ kí àwọn olùgbà ìrànwọ́ yi lè dúró lórí ẹsẹ̀ ara wọn,lai will ju ẹnikẹ́ni.
NÀÌJÍRÍÁ WÀ LỌ́NÀ TÓ DÁRA
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ipò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà, Hon Awude fi ìrètí rẹ hàn, nípa ọ̀nà tí orílẹ̀-èdè Náijiria ń gbà lọ.
Ó tọ́ka sí àwọn èrò àwọn àgbà onímọ̀ ọrọ̀ ajé olókìkí bi Prof. Charles Soludo àti Dókítà Ngozi Okonjo-Iweala, pé ọrọ̀ ajé Nàìjíríà ń lọ sí ọ̀nà tí kì ó lè jẹ́ alágbára àti aláfọkantan fún ọjọ́ iwájú.
Ó sọ pé àwọn ìṣòro ọrọ̀ ajé tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń dojú kọ bayi jẹ́ àbájáde àwọn àtúnṣe tó lágbára èyí tí Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu gbé kalẹ̀ láti kojú àwọn ìṣòro tó ti pẹ́, tí ó ń dojú kọ ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè wa, àti láti tún ọrọ̀ ajé na ṣe kí a lè jẹ pẹ títí.
Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, àṣeyọrí àwọn àtúnṣe bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ àfihàn nípa ipa tí wọ́n máa ní lórí ìgbésí ayé àti oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń yoo gbà láti má rí owó pá wọlé ní ọjọ́ iwájú.
AWUDE GBÉ ORÍYIN FÚN HON OLUBUNMI TUNJI-OJO (BTO) GIDI GAN NÍ
Ọ̀gbẹ́ni Dayo Awude tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Minisita fún ọrọ Abẹ́lé,Hon Olubunmi Tunji-Ojo(BTO), fún àtìlẹ́yìn àti ìfarajìn rẹ̀ sí ìdàgbàsókè SGN àti àwọn ètò ìrànwọ́ tí àjọ náà ń ṣe ní ìpele àwọn ará ìlú.
Ó ṣàpèjúwe Tunji-Ojo gẹ́gẹ́ bí aṣáájú tó lóye pàtàkì,tí ó sì nwa Ìlọsíwájú ìdàgbàsókè rere fun àwọn ènìyàn,
Ó wi pe Tunji-Ojo jẹ́ ẹni tí ó ńṣe àtìlẹ́yìn gidi fún àjọ SGN,èyí tí atilẹyin na mú kí ajọ na má ṣe dáadáa sí nl ibi gbogbo tí ó sì njẹ ki o lagbára láti mú àwọn ètò rẹ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn àwùjọ púpọ̀ sí i káàkiri Ìpínlẹ̀ Ondo.
SGN TÚN FÌDÍ ÌFARAJÌN RẸ̀ MÚLẸ̀ FÚN ÀWỌN ARÁ ÌLÚ
Nígbà tó ń parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ọ̀gbẹ́ni Awude tún fìdí ìfarajìn SGN múlẹ̀ SÍ fun ìdàgbàsókè àwọn ènìyàn àwùjọ àti sí àtìlẹ́yìn àwọn ètò tó ń ní ipa rere lórí ìgbésí ayé àwọn ènìyàn tí ó kú diẹ kaato fun.
Ó ní SGN máa tẹ̀síwájú láti bá ìran Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu mu, nígbà tó máa ń dojú kọ́ gbígbé iṣẹ́ ìdàgbàsókè,lroni lágbára àti ìrànwọ́ sún mọ́ àwọn ènìyàn tẹsiwaju si.
Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ lórí Eto orí Rẹdio Viral 98.5FM Àkúré yi,bí ó ṣe sọ nípa àwọn iṣẹ́ tó wà nílẹ láti ṣe,èyí tí Ajọ SGN yóò ṣe ní ìpele ni ipele fun àwọn ará ìlú.
O wa pari ọ̀rọ̀ rẹ lórí Eto na bayi pe:
Òrùlé gbọ́dọ̀ máa dáàbò bo ẹrù Inú rẹ ní gbogbo ìgbà
Orísun iròyìn YI ni
“SGN Media team”
Awise Sunday Agbaje Jagi,lọ kò ìròyìn na jọ fún ìwé ìròyìn Dingi Oòduà.
DingiOoduatv’26
